< תהילים 94 >

אֵל־נְקָמוֹת יְהוָה אֵל נְקָמוֹת הוֹפִֽיעַ׃ 1
Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
הִנָּשֵׂא שֹׁפֵט הָאָרֶץ הָשֵׁב גְּמוּל עַל־גֵּאִֽים׃ 2
Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n.
עַד־מָתַי רְשָׁעִים ׀ יְהוָה עַד־מָתַי רְשָׁעִים יַעֲלֹֽזוּ׃ 3
Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwa tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀?
יַבִּיעוּ יְדַבְּרוּ עָתָק יִֽתְאַמְּרוּ כָּל־פֹּעֲלֵי אָֽוֶן׃ 4
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde; gbogbo àwọn olùṣe búburú kún fún ìṣògo.
עַמְּךָ יְהוָה יְדַכְּאוּ וְֽנַחֲלָתְךָ יְעַנּֽוּ׃ 5
Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
אַלְמָנָה וְגֵר יַהֲרֹגוּ וִֽיתוֹמִים יְרַצֵּֽחוּ׃ 6
Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.
וַיֹּאמְרוּ לֹא יִרְאֶה־יָּהּ וְלֹא־יָבִין אֱלֹהֵי יַעֲקֹֽב׃ 7
Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
בִּינוּ בֹּעֲרִים בָּעָם וּכְסִילִים מָתַי תַּשְׂכִּֽילוּ׃ 8
Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn; ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
הֲנֹטַֽע אֹזֶן הֲלֹא יִשְׁמָע אִֽם־יֹצֵֽר עַיִן הֲלֹא יַבִּֽיט׃ 9
Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
הֲיֹסֵר גּוֹיִם הֲלֹא יוֹכִיחַ הַֽמְלַמֵּד אָדָם דָּֽעַת׃ 10
Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí? Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
יְֽהוָה יֹדֵעַ מַחְשְׁבוֹת אָדָם כִּי־הֵמָּה הָֽבֶל׃ 11
Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
אַשְׁרֵי ׀ הַגֶּבֶר אֲשֶׁר־תְּיַסְּרֶנּוּ יָּהּ וּֽמִתּוֹרָתְךָ תְלַמְּדֶֽנּוּ׃ 12
Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,
לְהַשְׁקִיט לוֹ מִימֵי רָע עַד יִכָּרֶה לָרָשָׁע שָֽׁחַת׃ 13
Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
כִּי ׀ לֹא־יִטֹּשׁ יְהוָה עַמּוֹ וְנַחֲלָתוֹ לֹא יַעֲזֹֽב׃ 14
Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
כִּֽי־עַד־צֶדֶק יָשׁוּב מִשְׁפָּט וְאַחֲרָיו כָּל־יִשְׁרֵי־לֵֽב׃ 15
Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo, àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.
מִֽי־יָקוּם לִי עִם־מְרֵעִים מִֽי־יִתְיַצֵּב לִי עִם־פֹּעֲלֵי אָֽוֶן׃ 16
Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú? Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
לוּלֵי יְהוָה עֶזְרָתָה לִּי כִּמְעַט ׀ שָֽׁכְנָה דוּמָה נַפְשִֽׁי׃ 17
Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
אִם־אָמַרְתִּי מָטָה רַגְלִי חַסְדְּךָ יְהוָה יִסְעָדֵֽנִי׃ 18
Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
בְּרֹב שַׂרְעַפַּי בְּקִרְבִּי תַּנְחוּמֶיךָ יְֽשַׁעַשְׁעוּ נַפְשִֽׁי׃ 19
Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
הַֽיְחָבְרְךָ כִּסֵּא הַוּוֹת יֹצֵר עָמָל עֲלֵי־חֹֽק׃ 20
Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
יָגוֹדּוּ עַל־נֶפֶשׁ צַדִּיק וְדָם נָקִי יַרְשִֽׁיעוּ׃ 21
Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
וַיְהִי יְהוָה לִי לְמִשְׂגָּב וֵאלֹהַי לְצוּר מַחְסִֽי׃ 22
Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.
וַיָּשֶׁב עֲלֵיהֶם ׀ אֶת־אוֹנָם וּבְרָעָתָם יַצְמִיתֵם יַצְמִיתֵם יְהוָה אֱלֹהֵֽינוּ׃ 23
Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

< תהילים 94 >