< Hebræos 9 >

1 Habuit quidem et prius, iustificationes culturae, et Sanctum saeculare.
Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí.
2 Tabernaculum enim factum est primum, in quo erant candelabra, et mensa, et propositio panum, quae dicitur Sancta.
A gbé àgọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́.
3 Post velamentum autem secundum, tabernaculum, quod dicitur Sancta sanctorum:
Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jùlọ;
4 aureum habens turibulum, et arcam testamenti circumtectam ex omni parte auro, in qua urna aurea habens manna, et virga Aaron, quae fronduerat, et tabulae testamenti,
tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;
5 superque eam erant Cherubim gloriae obumbrantia propitiatorium: de quibus non est modo dicendum per singula.
àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i síji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.
6 His vero ita compositis: in priori quidem tabernaculo semper introibant sacerdotes, sacrificiorum officia consummantes:
Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkígbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.
7 in secundo autem semel in anno solus pontifex non sine sanguine, quem offerret pro sua, et populi ignorantia:
Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìṣìnà àwọn ènìyàn.
8 hoc significante Spiritu sancto, nondum propalatam esse sanctorum viam, adhuc priore tabernaculo habente statum.
Ẹ̀mí Mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà Ibi Mímọ́ Jùlọ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkínní bá sì dúró,
9 quae parabola est temporis instantis: iuxta quam munera, et hostiae offeruntur, quae non possunt iuxta conscientiam perfectum facere servientem, solummodo in cibis, et in potibus,
èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí. Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé.
10 et in variis baptismatibus, et iustitiis carnis usque ad tempus correctionis impositis.
Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.
11 Christus autem assistens pontifex futurorum bonorum, per amplius et perfectius tabernaculum non manufactum, id est, non huius creationis:
Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí.
12 neque per sanguinem hircorum, aut vitulorum, sed per proprium sanguinem introivit semel in Sancta, aeterna redemptione inventa. (aiōnios g166)
Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. (aiōnios g166)
13 Si enim sanguis hircorum, et taurorum, et cinis vitulae aspersus inquinatos sanctificat ad emundationem carnis:
Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:
14 quanto magis sanguis Christi, qui per Spiritum sanctum semetipsum obtulit immaculatum Deo, emundabit conscientiam nostram ab operibus mortuis, ad serviendum Deo viventi? (aiōnios g166)
mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè? (aiōnios g166)
15 Et ideo novi testamenti mediator est: ut morte intercedente, in redemptionem earum praevaricationum, quae erant sub priori testamento, repromissionem accipiant qui vocati sunt aeternae hereditatis. (aiōnios g166)
Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà. (aiōnios g166)
16 Ubi enim testamentum est: mors necesse est intercedat testatoris.
Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;
17 Testamentum enim in mortuis confirmatum est: alioquin nondum valet, dum vivit qui testatus est.
nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ́yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú, nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láààyè.
18 Unde nec primum quidem sine sanguine dedicatum est.
Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú pàápàá sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.
19 Lecto enim omni mandato legis a Moyse universo populo: accipiens sanguinem vitulorum et hircorum cum aqua et lana coccinea, et hyssopo: ipsum quoque librum, et omnem populum aspersit,
Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn.
20 dicens: Hic sanguis testamenti, quod mandavit ad vos Deus.
Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàṣẹ fún yín.”
21 Etiam tabernaculum, et omnia vasa ministerii sanguine similiter aspersit:
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.
22 Et omnia pene in sanguine secundum legem mundantur: et sine sanguinis effusione non fit remissio.
Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.
23 Necesse est ergo exemplaria quidem caelestium his mundari: ipsa autem caelestia melioribus hostiis quam istis.
Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́.
24 Non enim in manufacta Sancta Iesus introivit exemplaria verorum: sed in ipsum caelum, ut appareat nunc vultui Dei pro nobis:
Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa.
25 Neque ut saepe offerat semetipsum, quemadmodum Pontifex intrat in Sancta per singulos annos in sanguine alieno:
Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkígbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀,
26 alioquin oportebat eum frequenter pati ab origine mundi: nunc autem semel in consummatione saeculorum, ad destitutionem peccati, per hostiam suam apparuit. (aiōn g165)
bí bẹ́ẹ̀ bá ni, òun ìbá tí máa jìyà nígbàkígbà láti ìpìlẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. (aiōn g165)
27 Et quemadmodum statutum est hominibus semel mori, post hoc autem iudicium:
Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́,
28 sic et Christus semel oblatus est ad multorum exhaurienda peccata: secundo sine peccato apparebit omnibus expectantibus se, in salutem.
bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.

< Hebræos 9 >