< Aggæi Prophetæ 1 >

1 in anno secundo Darii regis in mense sexto in die una mensis factum est verbum Domini in manu Aggei prophetae ad Zorobabel filium Salathihel ducem Iuda et ad Iesum filium Iosedech sacerdotem magnum dicens
Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.
2 haec ait Dominus exercituum dicens populus iste dicit nondum venit tempus domus Domini aedificandae
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’”
3 et factum est verbum Domini in manu Aggei prophetae dicens
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé,
4 numquid tempus vobis est ut habitetis in domibus laqueatis et domus ista deserta
“Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”
5 et nunc haec dicit Dominus exercituum ponite corda vestra super vias vestras
Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.
6 seminastis multum et intulistis parum comedistis et non estis satiati bibistis et non estis inebriati operuistis vos et non estis calefacti et qui mercedes congregavit misit eas in sacculum pertusum
Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”
7 haec dicit Dominus exercituum ponite corda vestra super vias vestras
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.
8 ascendite in montem portate lignum et aedificate domum et acceptabilis mihi erit et glorificabor dicit Dominus
Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí.
9 respexistis ad amplius et ecce factum est minus et intulistis in domum et exsuflavi illud quam ob causam dicit Dominus exercituum quia domus mea deserta est et vos festinatis unusquisque in domum suam
“Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.
10 propter hoc super vos prohibiti sunt caeli ne darent rorem et terra prohibita est ne daret germen suum
Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde.
11 et vocavi siccitatem super terram et super montes et super triticum et super vinum et super oleum et quaecumque profert humus et super homines et super iumenta et super omnem laborem manuum
Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”
12 et audivit Zorobabel filius Salathihel et Iesus filius Iosedech sacerdos magnus et omnes reliquiae populi vocem Dei sui et verba Aggei prophetae sicut misit eum Dominus Deus eorum ad ipsos et timuit populus a facie Domini
Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa.
13 et dixit Aggeus nuntius Domini de nuntiis Domini populo dicens ego vobiscum dicit Dominus
Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí.
14 et suscitavit Dominus spiritum Zorobabel filii Salathihel ducis Iuda et spiritum Iesu filii Iosedech sacerdotis magni et spiritum reliquorum de omni populo et ingressi sunt et faciebant opus in domo Domini exercituum Dei sui
Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,
15 in die vicesima et quarta mensis in sexto mense in anno secundo Darii regis
ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.

< Aggæi Prophetæ 1 >