< 1 Timothy 5 >

1 Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.
不要嚴責老年人,但要他勸他如勸父親;勸青年人如勸弟兄;
2 Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.
勸老婦如勸母親;以完全的心,勸青年女子如勸姊妺。
3 Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́.
要敬重寡婦,即那些真正做寡婦的,
4 Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.
假使寡婦有兒子或孫子,她們就應學著孝敬本家人,報答祖先,因為這是天主所喜悅的事。
5 Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.
那真正做寡婦的,孤獨無依,已寄望於天主,黑夜白日常在懇求和祈禱;
6 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè.
但那任性縱慾的寡婦雖生猶死。
7 Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn.
你要拿這些話去勸戒,使她們無可指摘。
8 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.
如有人不照顧自己的戚族,尤其不照顧自己的家人,即是背棄信德,比不信的人更壞。
9 Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan.
錄用一個寡婦,年紀不要少過六十歲,且要只做過一個丈夫的妻子,
10 Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.
又必須有行善的聲望,教育過兒女,或款待過旅客,洗過聖徒的腳,賙濟過遭難的人,勤行過各種善工。
11 Ṣùgbọ́n ma ṣe kọ orúkọ àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà tiwọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kristi, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó.
至於年輕的寡婦,你要拒絕錄用,因為她們情慾衝動違背基督的時候,更想再嫁,
12 Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀.
這樣必招致懲罰,因為她們擯棄了起初的信誓;
13 Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ilédélé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ.
同時她們又游手好閒,習慣串門踏戶;不但游手好閒而且還饒舌不休,好管閒事,說些不當說的話。
14 Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábojútó ilé, kí wọn má ṣe fi ààyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.
所以失要年輕的寡婦再嫁,生兒育女,治理家務,不給敵以誹謗的任何藉口,
15 Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Satani.
因為有些已轉身隨從了撒殫。
16 Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.
女信徒家中有寡婦,就應供養她們,不可加重教會的負擔,為使教會能供養那些真正的寡婦。
17 Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni.
那些善於督的長老,首先那些出力講道和施教的人堪受加倍的敬奉
18 Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.”
因為經上記載:『牛在打場的時候,不可籠住牠的嘴;』又說:「工人自當有他的工資。』
19 Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta.
反對長老的控告,除非有兩三證個人,你不可受理。
20 Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù.
犯罪的人,你要在眾人前加以責斥,為叫其餘的人有所警愓。
21 Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.
我在天主於基督耶穌,以及蒙選的天使前懇事求你,要遵守這些話,不可存成見,做事也不可有偏心。
22 Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́.
不可輕易給人覆手:不可在別人的罪上有分子,務要守身清白。
23 Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.
至於你,你以後不要單喝清水,為了你的胃病和你屢次生病,卻要用點酒。
24 Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́; tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn.
有些人的罪過,在受審以前便是顯明的,但是有些人的罪過只在受審以後;
25 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba; bí wọn kò tilẹ̀ tí ì hàn, wọn kò lè fi ara sin títí.
同樣,善工也是顯明的;既使不明顯,也不能隱瞞住。

< 1 Timothy 5 >